Afárá

Afárá jẹ́ ohun kíkọ́ kan tí wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ láti gba orí ǹkan bíi omi tàbí kòtò tí ó ń dínà mọ́ni kọjá, kí lílọ bíbọ̀ àwọn ǹkan mìíràn bíi ọkọ̀, rélùwéè, àwọn ènìyàn àti ǹkan míràn lè ma kọjá geere lórí rẹ̀. Púpọ̀ àwọn afárá ni wọ́n ma ń rí pẹrẹsẹ , tí àwọn opó ńlá ńlá ma ń dìí mú pọ̀ mọ́ àwon áàkì pẹ̀lú àwọn wáyà onírin ńlá ńlá ma ń dìí mú pẹ̀lú. Afárá ma ń dúró lé orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n fi ọgbọ́n gbé kalẹ̀ kí ó lè gba ẹrù afárá náà dání lórí ilẹ̀.
A lè kọ́ àwọn afárá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà àti irúfẹ́, èyí tí ó máa ń dá lórí ibi tí a fẹ́ kọ́ afárá náà sí, ohun tí a fẹ́ lò ó fún, àti àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ ìkọ́lé tí ó wà ní ìlò. Àwọn irúfẹ́ afárá tó rọrùn jù lọ ni afárá igi tí a lè fi àwọn ẹ̀ka tàbí igi gígùn ṣe, àti afárá adúró-sókè tí a lè fi okùn tàbí àwọn àjàrà ṣe.Àwọn Róòmù àti àwọn ará Ṣáínà ìgbàanì kọ́ àwọn afárá tó ṣe pàtàkì gan-an, pàápàá jùlọ àwọn afárá ìgún-ọnà . Wọ́n máa ń lo igi, òkúta àti bíríkì láti kọ́ irú àwọn afárá bẹ́ẹ̀.
Pẹ̀lú Ìyípadà Iṣẹ́ Ọ̀nà, irin bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe jáde ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, èyí sì jẹ́ kí ó ṣeé ṣe láti kọ́ àwọn afárá tó ní àwọn ìrísí tó díjú síi. Àwọn irúfẹ́ bẹ́ẹ̀ ni afárá turusi àti afárá kantivali . Àwọn irú afárá wọ̀nyí jẹ́ kí ó ṣeé ṣe láti kọjá lórí àwọn odò tó fẹ̀ tàbí àwọn àfonífojì tó jinlẹ̀.
| Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
Itokasi
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]| Wikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Afárá |